Jump to content

Okoho

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àtúnyẹ̀wò ní 14:11, 2 Oṣù Bélú 2024 l'átọwọ́ 102.89.69.156 (ọ̀rọ̀)
(ìyàtọ̀) ← Àtúnyẹ̀wò tópẹ́ju | Àtúnyẹ̀wò ìsinsìnyí (ìyàtọ̀) | Àtúnyẹ̀wò tótuntunju → (ìyàtọ̀)

Okoho

Okoho ni ó jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ tí a mọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Idoma people ti Benue State, Àárín gbùngbùn Nàìjíríà . A sé láti ara ohun ọ̀gbìn Cissus populnea tí ó jẹ́ ọmọ ẹbí Amplidaceae (Vitaceae).[1]

Ó jẹ́ ọbẹ̀ tí a ṣe láti ara igi Okoho eléyìí tí ó máa ń yọ̀ gidi gan-an lẹ́yìn ṣíṣè rẹ̀. Wọ́n sábàá máa ń sè é pẹ̀lú ẹran ìgbẹ́ bush meat (gẹ́gẹ́ bí ọ̀yà, àwọ̀n àti ẹran sísun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ)ó sì máa ń jẹ́ gbígbádùn ní jíjẹ jù pẹ̀lú iyán (aka Onihi).A tún lè jẹ́ pẹ̀lú sẹ̀mó semolina, eba (tí a ṣe láti ara gààrí garri) àti èlùbọ́ . Wọ́n sábàá máa ń ṣe ọbẹ̀ náà láìlo epo. Òun ni oúnjẹ tí ó ní ìbọ̀wọ̀ fún jù lọ tí wọ́n sì ń bèèrè fún jù lọ ní gbogbo ayẹyẹ Idoma gẹ́gẹ́ bí ; ìgbéyàwó ìbílẹ̀, ayẹyẹ òkú ṣíṣe, ọjọ́ ìbí àti àwọn ọdún mìíràn. Ọbẹ̀ Okoho jẹ́ asaralóooore ó sì tún jẹ́ mímọ̀ fún jíjẹ́ kí oúnjẹ dà.[2] Àwọn ẹ̀yà Nàìjíríà yòókù bí Ìgbò àti Ìgalà náà tún máa ń pè é ní Okoho,[3] nígbà tí igi náà jẹ́ mímọ̀ sí Ajara tàbí Orogbolo fún ẹ̀yà Yorùbá ti àríwá àti gúsù Nàìjíríà. Àwọn Hausas sábàá máa ń pè é ní Dafara.[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

  1. 1.0 1.1 Ibrahim, H; Mdau, B B; Ahmed, A; Ilyas, M (December 30, 2010). "Anthraquinones of Cissus Populnea Guill & Perr (Amplidaceae)". African Journal of Traditional, Complementary and Alternative Medicines 8 (2): 140–143. doi:10.4314/ajtcam.v8i2.63200. PMC 3252698. PMID 22238494. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3252698. 
  2. "How to Make Okoho Soup | cookbakingtips". cookbakingtips.com.ng. Archived from the original on 2016-08-28. Retrieved 2016-08-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Cissus Populnea & Irvingia Gabonensis : Comparative Study On Acceptability As Soup Thickner". doublegist.com. Archived from the original on 2024-04-30. Retrieved 2016-08-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)