Han Hye-jin (oṣere)
Han Hye-jin tí wọn bí ní ọjọ́ kẹtàdínlógún osù kẹwàá ọdún 1981 jẹ́ òṣèré South Korea. Han di ìlúmọ̀ọ́ká fùn ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré-oníṣe kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Be Strong, Geum-soon gẹ́gẹ́ bí opó. Lára àwọn eré-oníṣe tó lààmì-laaka tí ó ti kópa ni Jumong tí ó kópa gẹ́gẹ́ bí Soseono, Jejungwon tí ó kópa gẹ́gẹ̀ bí oníṣègùn òyìnbó, 2626 years níbi tí ò ti kópa gẹ́gẹ̀ bí òǹyìnbọn atamátàsé. Bákan náà ni ó tún jẹ̀ olò̀òtú ètò kan tí ó pè ní Healing Camp, Aren't You Happy? láàrín ọdùn 2011 sí ọdún 2013. [1] [2]
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Han àti òǹkọrin Naul tí ó jẹ́ olórin R&B ní ìbáṣepọ̀ ní ǹkan bí ọdún 2003 sí ọdún 2012. [3] [4]
Han sì tún fi ìdí́ rẹ̀ múlẹ̀ nínú oṣù kẹta ọdún 2013 wipé òun ní ibáṣèpọ̀ pẹ̀lú agbábọ́ọ̀lù ọwọ́ àárìn fún orílẹ̀-èdè South Korean, ìyẹn Ki Sung-Yeung, tí wọ́n sì kéde ìgbéyàwó wọn ní inú oṣù kejì lẹ́yìn rẹ̀ [5] [6] [7] Àwọn méjèèjì ṣe igbeyawo ni ọjọ kinni oṣu kehe odún 2013, wón sì bí ọmọbìnrin kan ní ọjọ́ ketàlá oṣù kesànán ọdún 2015olùfọkànsìn. Àwọn ni wọ́n ní ile-itura Hotel Intercontinental Seoul. [8]