Jump to content

Ìpínlẹ̀ Anambra

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ẹ̀dà aṣeétẹ̀jáde kò ṣe é lò nínú, ó sì lè ní àṣìṣe àmúlò. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣe àtúnmúkójúùwọ̀n fún aṣèrántí-ojú-ìwé ẹ̀rọ-àṣàwárí, dákun, ṣàmúlò ìlò títẹ̀jáde ìpìlẹ̀ ti ẹ̀rọ-àṣàwárí dípò bẹ́ẹ̀.
Anambra
Anambra State.
Anambra State.
Nickname(s): 
Location of Anambra in Nigeria
Location of Anambra in Nigeria
Country Nigeria
Date created27 August 1991
CapitalAwka
Government
 • Governor[1]Charles Chukwuma Soludo (APGA)
Area
 • Total4,844 km2 (1,870 sq mi)
Area rank35 of 36
Population
 (2006 census)1
 • Total4,055,048
 • Rank10 of 36
 • Density840/km2 (2,200/sq mi)
GDP (PPP)
 • Year2007
 • Total$6.76 billion[2]
 • Per capita$1,585[2]
Time zoneUTC+01 (WAT)
ISO 3166 codeNG-AN
Websiteanambrastateng.org
^1 Preliminary results

Ìpínlẹ̀ Anambra jẹ́ ìpínlẹ̀ kan láàárín àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní agbègbè gúúsù-ìlà-oòrùn orílẹ̀ èdè náà.[3] Wọ́n dá ìpínlẹ̀ náà lẹ̀ ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọdún 1991.[4] Ìpínlẹ̀ Anambra sopọ Ìpínlẹ̀ Delta sí ìwọ̀-oòrùn, Ìpínlẹ̀ Imo sí gúúsù, Ìpínlẹ̀ Enugu sí ìlà-oòrùn ̀ti Ìpínlẹ̀ Kogi sí àríwá.[5]

Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ètò-ìkànìyàn ọdún 2022 àwọn olugbe tí wọn tó mílíọ́nnù mẹ́sàn-án ni wọ́n gbé ní Ìpínlẹ̀ náà.[6] Orukọ Ìpínlẹ̀ náà ni wọ́n ṣàwárí ní ọdún 1976 látara àáríngbùngbùn ìlà-oòrùn Ìpínlẹ̀ náà, wọ́n fún Ìpínlẹ̀ náà lórúkọ ní ìbámu pẹ̀lú Odò Omambala, odò tó ń sàn jákèjádò ìpínlẹ̀ náà. Anambra jẹ́ orúkọ àyálò ti Omambala.[7][8] Olú-ìlú rẹ̀ ni Awka, ìlú tó ń gbòrò ní kíákíá tí èrò inú rẹ̀ ti lé si láti Ẹgbẹ̀rún-lọ́nà-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin sí mílíọ́nnù mẹ́fà láàárin ọdún 2006 sí 2020. Ìlú Onitsha, tí ó jẹ́ ibùdó ìlú nínú ìtàn láti ìgbà ìmúnisìn àwọn aláwọ̀-funfun, ṣì jẹ̀ ọ̀gangan ìṣòwò láàárin Ìpínlẹ̀ náà..[9]

Orúkọ-ìnagijẹ rẹ̀ ni "Ìmọ́lẹ̀ orílẹ̀ èdè" "Light of the Nation", Ìpínlẹ̀ Anambra jẹ́ ìpínlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ tí ó gbòòrò jùlọ ní ààyè tàbí agbègbè [10] ní orílẹ̀ èdè, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé ìdijú-jiyàn rẹ̀ wà pèlu Onitsha, agbègbè tí ó tóbi jùlọ tí ó sì pọ̀ ni èrò nínú ìgboro tí àwọn èèyàn inú rẹ̀ tó mílíọ́nnù mẹ́jọ-àbọ̀ ni wọ́n ti ṣàwárí gẹ́gẹ́ bí àbájáde Africapolis ti ọdún 2020 tí ó mú Onitsha jẹ́ ìgboro-ìlú ẹlẹ́kejì tí ó gbòòrò jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní iye àti ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ta ní ilẹ̀-adúláwọ̀.[11] Bakan naa gẹ́gẹ́ bí àbájáde àwọn Demographia ti ọdún 2019 ìgboro Onitsha ẹlẹ́ẹ̀kẹtàdínláàdọ́ta ìgboro-ìlú tí ó tóbi jùlọ lágbàáyé pẹlu èro mílíọ́nnù mẹ́jọ Anambra jé Ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ẹ̀kejì ní kíkéré ni agbègbè ni.[12][13] Agbègbè tí a mọ̀ sí Ìpínlẹ̀ Anambra ti jẹ́ agbègbè tí ó lajú ókérétán láti bíi ẹlẹ́èkẹsàn ọgọ́rù-únn AD, pẹ̀lú ìlú àbáláyé Nri, ti olú-ìlú rè jẹ́ Igbo-Ukwutẹ́lẹ̀rí nínú ìtàn láàárin Ìpínlẹ̀ náà. Àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Anambra jé àwọnIgbo,[14][15] pẹ̀lú èdè Igbo tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí èdè àjùmọ̀ lò jákèjádò ìpínlẹ̀ náà.[16]


Itokasi

  1. See List of Governors of Anambra State for a list of prior governors
  2. 2.0 2.1 "C-GIDD (Canback Global Income Distribution Database)". Canback Dangel. Retrieved 2008-08-20. 
  3. "Anambra | state, Nigeria | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-12. 
  4. "Anambra State". Nigerian Investment Promotion Commission (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-01-07. Retrieved 2022-05-16. 
  5. "Anambra State of Nigeria :: Nigeria Information & Guide". www.nigeriagalleria.com. Retrieved 2022-05-20. 
  6. "Nigeria Census - Nigeria Data Portal". 
  7. Grid 3, Nigeria. "Anambra". Archived from the original on 26 September 2022. Retrieved 26 June 2022. 
  8. Ezenwa-Ohaeto, Ngozi (2013). "Sociolinguistic import of name-clipping among Omambala cultural zone in Anambra state". Creative Artist: A Journal of Theatre and Media Studies 7 (2): 111–128. https://www.ajol.info/index.php/cajtms/article/view/117032. 
  9. "Onitsha | Location, Facts, & Population | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-12. 
  10. "Top 10 Most Populated States in Nigeria (2022)". Archived from the original on 2022-08-30. Retrieved 2022-08-30. 
  11. "Top 50 Agglomerations in Africa". Africapolis. |
  12. Ndulue, Ayadiuno, Dominic Chukwuka, Romanus Udegbunam (2021). "PRINCIPAL COMPONENT ANALYSIS OF FACTORS INFLUENCING MODE OF MOVEMENT IN ANAMBRA STATE, SOUTH EAST NIGERIA". Turkish Journal of Physiotherapy and Rehabilitation 32 (3): 3837–3848. https://www.researchgate.net/publication/352166052. 
  13. World, Population Review (2022). "Population of Cities in Nigeria (2022)". Retrieved 26 June 2022. 
  14. "Anambra State – SENDEF" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-06-03. Retrieved 2021-03-09. 
  15. "The Igbo, sometimes (especially formerly) referred to as Ibo, are one of the largest single ethnicities in Africa". faculty.ucr.edu. Retrieved 2021-03-09. 
  16. Onumajuru, V. C. (2016-06-06). "A contrastive study of two varieties of Onicha and the Central Igbo language" (in en). AFRREV IJAH: An International Journal of Arts and Humanities 5 (2): 225–240. doi:10.4314/ijah.v5i2.18. ISSN 2227-5452. https://www.ajol.info/index.php/ijah/article/view/137075.