Edgar Adrian
Edgar Adrian, 1st Baron Adrian | |
---|---|
Ìbí | Edgar Douglas Adrian 30 Oṣù Kọkànlá 1889 Hampstead, London, England |
Aláìsí | 4 August 1977 Cambridge, Cambridgeshire | (ọmọ ọdún 87)
Ọmọ orílẹ̀-èdè | United Kingdom |
Pápá | Electrophysiology |
Ilé-ẹ̀kọ́ | Cambridge University |
Ibi ẹ̀kọ́ | Cambridge University |
Edgar Douglas Adrian nịọgbọ́njo osu kọkànlá Ọdún 1889 (11-30-1889). A bi I ni ilú Hampstead, London, England. O kú ní ọjọ́ kẹ̣rin oṣú kẹjọ ọdún 1977 (ní ìgbà naa o jẹ́ ọmọ dun mẹ́ta-di-ni-aadọrun-un).
O jẹ́ ará ìlu British tí o jẹ́ onímọ ifero mo-ise-ohun-ẹlẹ́mi ati ólùgbà ebùn íyibíye ọlọ́lá ni ọdún 1932 fún ìmọ ìse ohun ẹlẹmi ti oun àti Sir Charles Sherrigbon jùmọ̀ jẹ́ fún ìmúlò oun kan nínú ara tí o má gbé ìròyin làtí ibi opolo de ibi-ti-o kú lárá.
Ọmọ Alfred Douglas Adrian, onimọran ofin fún igbimọ ijọba ibíle tí BriitiṣI (British) ni ojogbon Edgar je. Ọ̀jọ̀gbọ́n Edger Adrian lo si ile-ìwe West Minister, o si ká sáyẹ́ǹsì adándá ni ilé-ìwé gíga ti Kémíbiriijì. O si wa ni ibè fún opolopo odun. O parí kí kọ́ ìmọ̀ egbógi ni ọdun 1915. Iṣé aseparí fun eko wọn ti ile-wosan ni o se ni ile-Iwosan ti St. Bartholemew’s ni London nigba ogun agbaye kiini, O se ìtọ́jú àwọn ológun. Ọ̀jọgbọ́n Edger pada si Kémíbirììji ní ọdun 1919, ni igba ti o di ọdun 1925. Ọ̀jọ̀gbọ́n Adrian Baron fẹ́ Arabirin HESTER AGNES PINSENT ni ọjọ́ ḳẹrin-la osu kẹta ọdun 1923 (14-6-1923). Won bi ọmọ mẹ̣́ta (ọmọ obinrin kan àti awọn Ibejí miiran). Ọ̀jọ̀gbọ́n Adrian se awárì elétirìiki nínú ẹ̀yá ara níbí isan.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |